Ìbídámipé Oun gbogbo ti dojúrú tán bàyíí ní ìlú èdá, Eku kò, kó ké bí eku, Béè sìni eye kò kó ké bí eye móó, Oun gbogbo ti dòbírípo, Ìrònú dorí àgbà kodó, Sùgbón; ewo àwon èwe àti ìpéèrè bìi wón ti n yótòmì, Àfi bíi omo tí ìyá rè sèsè papò dà re bi àgbà nrè, Umn! Ótojú sú ni, nínú ìlú èdá, Kíni kí a se? Àwon àgbàgbà ìlú foríkorí láti to elédùà lo, Elédùà seun, ònà àbáyo ti dé! Kí wá ni ònà àbáyo òún o? Ìbídámipè! Ìbídámipé ni ònà àbáyo. Tani ìbídámipé? Ìbídámipé ni; Àjòjì arewà aláboyún kan, Tí yiò wo inú ìlú Èdá wá láìròtélè, Tí ó ba tí leè bí omo inú rè sínú ìlú Èdá bàyí; ìlú yíò tùbà, yíò sì tùse, Oun gbogbo yíò bòsípò fún gbogbo ènìà, Kòpé kòjìnà, Arewà aláboyún kan wo inú ìlú wá, Ní pasè ìtóni amòye, Amò wípé arewà aláboyún yìí ni gbogbo ìlú ti nretí, Ní kété tí oùn yí balè, Gbogbo ará ìlú, terú tomo, tolórí telèmò, Tonílé tàlejò bá bèrè sí níí keé ìbídámipé bíi omo titun, Oba ìlú Èdá tilè fún ìbídámipé nì ilé nlá alárànbarà kan láti máa gbé, Nínú ilé ...