Á n gbòròmodìe lówó ikú,
Óní akò jé kí òun ràkìtàn lojè,
Ló dífá fún ìwo òdó tí aso fún wípé;
Òwúrò lojó eni bá máa ríre,
Tí òún mí sínú wípé;
Sèbí oòrùn tó wá lokè tóó sá aso gbe,
Ìwo ti gbàgbé nì wípé;
Eni bá kókó dójà ní máa kókó tà,
Béè sìni ó dára láti sá aso gbe nì òwúrò
Kí asì wòó ní òsán
Jù kí asèsè máa fo aso ní òsán, àkókò òde,
Oun gbogbo ni àkókò wà fùn,
Ìgbà ara báàyí làá búra nítorí;
Enìkan kìí bú sàngó nígbà èrùn,
Nítorínà ìwo òdó, múra sísé owó re,
Sisé nígbàtí egungun re ní okun,
Kí o má bàá fi ewú orí sisé nígbà tí ó báye kí o máa simi.
Wonderful wrIte up
ReplyDelete