Oun gbogbo ti dojúrú tán bàyíí ní ìlú èdá,
Eku kò, kó ké bí eku,
Béè sìni eye kò kó ké bí eye móó,
Oun gbogbo ti dòbírípo,
Ìrònú dorí àgbà kodó,
Sùgbón; ewo àwon èwe àti ìpéèrè bìi wón ti n yótòmì,
Àfi bíi omo tí ìyá rè sèsè papò dà re bi àgbà nrè,
Umn! Ótojú sú ni, nínú ìlú èdá,
Kíni kí a se?
Àwon àgbàgbà ìlú foríkorí láti to elédùà lo,
Elédùà seun, ònà àbáyo ti dé!
Kí wá ni ònà àbáyo òún o?
Ìbídámipè! Ìbídámipé ni ònà àbáyo.
Tani ìbídámipé?
Ìbídámipé ni;
Àjòjì arewà aláboyún kan,
Tí yiò wo inú ìlú Èdá wá láìròtélè,
Tí ó ba tí leè bí omo inú rè sínú ìlú Èdá bàyí;
ìlú yíò tùbà, yíò sì tùse,
Oun gbogbo yíò bòsípò fún gbogbo ènìà,
Kòpé kòjìnà,
Arewà aláboyún kan wo inú ìlú wá,
Ní pasè ìtóni amòye,
Amò wípé arewà aláboyún yìí ni gbogbo ìlú ti nretí,
Ní kété tí oùn yí balè,
Gbogbo ará ìlú, terú tomo, tolórí telèmò,
Tonílé tàlejò bá bèrè sí níí keé ìbídámipé bíi omo titun,
Oba ìlú Èdá tilè fún ìbídámipé nì ilé nlá alárànbarà kan láti máa gbé,
Nínú ilé yìí ni àwon olorì àti agbèbí ti nsètójú Ìbídámipé,
Ìbídámipé! Èmí ìlú wá dowóò re báyìí o...
Sùgbón kíi ìbídámipé balè bí omo inú rè labiye,
Ógbòdò tèlé gbogbo òfin tí elédùà fun láì yòkan kúrò,
Béè, ìbídámipé kìí je èso tí elédùà wífun kí ó máa je,
Nítorípé èso òún kò dùn lènu,
Báwo ni káse su orí omo tó tóbi báyìí o?
Àwon àgbà síbò, wón ní;
Ení bá máa jeun gboingboin, ógbòdò tilèkù gboingboin,
Tótúmò sí wípé...
Tíìbídámipé báfé sòóre, ógbòdò fi pèlékùtù je èso òún, bí ó ti wù kì ó korò tó.
Umn...
Ojó n gorí ojó, àkókò n fò bíi eye idì,
Oyún ìbídámipé ti yára dàgbà nïyen,
Àmó àkókò ìgbà bíbíi rè kò ti dé,
Sàdédé ni ìbídámipé yan òré àjòjì kan láàyò,
Sèbí akúkú mò wípé òré wa kò féràn èso tí elédùà ní kí ó máa je,
Ní se ni ó bá kúkú nfi èhónú rè ràn fún òré rè tuntun yi ní gbogbo àsìkò ìpàdée won,
Òré rè yí lo gbàá nímòràn láti máse je èso kíkorò yí mó,
Ó wípé, ìfìyà jeni àti ìfini sínú ìdè gbáà ni jíje èso kíkorò yí jé fún aláboyún,
Ó fi ìbídámipé lókan balè wípé: wéré laó gbòó!
Báwo ni káti só, ìbídámipé, ìrètí ìlú ti kò láti máa je èso bíwéré.
Níkété tí àwon àgbà ìlú sàkíyèsí ìwà tuntun ìbídámipé,
Wón sèkìlò, sùgbón kàkà kí ìbídámipé ye ìkìlò yí wò,
Níse ló jùú sínúu àgbàrá òjò,
Ó kotí ògboin sí àmòràn àwon àgbà,
Nígbà tí àwon àgbà ri wípé òrò ìbídámipé ti dà béèbéè,
Wón fi sílè fún ìfé inú ara rè,
Nígbà ó tilè jé wípé òré rè ti ba wá èso aládìídùn tí yíò máa je dípò,
Èso aládìídùn yìí lówá yí okàn ìrètí ìlú padà pátápátá,
Dipo èso tí Elédùà yàn fún ìbídámipé, óféràn èso tí òré àjòjì fún un,
Lósànkan-òrukan, ìbídámipé sálo kúro láàrin ìlú gege àmòràn òré rè,
Òré rè jékó ye wípé, tí ó bá sálo;
Àwon ará ìlú yíò wá olúgbálâ míràn fún ara won...
Ìbídámipé seti òré rè re tuntun,
O sa kúrò nínú ìlú èdá,
Ówípé; ogun másu-mátò won ti pò ju èmí òun lo.
Òrò ìbídámipé wá dàbí òrò òròmodìe,
À ngbòròmodìe lówó ikú, óní akò jé kí òun ràkìtàn lojè.
Kété tí àwon ará ìlú sàkíyèsí ìsèlè yí,
Wón fi tó Oko ìlú létí,
Inú Oba kòdùn sí ìsèlè yíì,
Ó pàse fún gbogbo ènìà-àn láti sàwárí ìrètí ìlú...
Òrò Oba lómú kí terú tomo ó fán ká sínúu gbogbo igbó tówà lágbègbè ìlú láti wá ìbídámipé,
Moti ri ò! Okàn lára àwon ode pariwo láàrín igbó,
Òún ni ó tajú kán tí ó rí ìbídámipé níbi tí ósùn gbalaja sí,
Àwon obìrin ati àwon agbèbí ló kókó gbó nítorí won kò jìnà sí arákùnrin oun,
Wón súré lo síbi tí ohún náà ti jáde,
Bíi wónti rí ìbídámipé níbi tí órè si, wón súré fi ìró won pakà yiká,
Ah! Àkókò ìgbà bíbíi rè ti tó, olórí àwon agbèbí lahùn,
Àwon agbèbí bèrè ìgbìyànjú won lórí ìbídámipé bí gbogbo obìrin ti dòyì yí won ká,
Ewo bìi àwon okùrin àti àwon olóyè ìlú se nforí sora láti wá ìgbín kí ìbídámipé ba leè bí wéré,
Ahhhh! Aruwo nlá yìí ló léwon léré padà,
Kílódé? Kíló selè?
Uum!
Èèmò dé! Nkan se!
Agbè fó! Omi inú rè dànù!
Ìrètí pin!
Ojú òrun yípadà sí dúdú lésèkesè,
Ìrù kèrè jábó lówó Oba láàfin,
Àgbàrá omi ekún nsàn lóju gbogbo ènìà-àn,
Ah! Ìbídámipé jáwa kulè nigbe tí wón ké bí wón ti n fi ìbìnújé gbé òkúu rè padà sàarin ìlú,
Ìbá se wípé ó tè sí ìtóni Elédùà ni,
Ìbídámipé kò báti mafi ikú sèfàje,
Ìbá fi ayò bí omo inú rè,
Ìbídámipé dalè, ójá àwon tí nretí ògo rè kulè,
Ófi èmí ara re sòfò.
Kí èyí jé èkó fún gbogbo òdó,
Àwon ìran-án re nretí ògo rè, wón fé mu nínu olà re gègè bí Elédùà ti sètò rè,
Àmón, sé ìwo náà kòti màa wùwà bíi ti ìbídámipé bàyíí?
Tì obáfé bí wéré, ógbòdò faramó ìkorò èso bíwéré, tííse;
Ìfara eni jì, ìkó ra eni ní ìjánu àti àfojúsùn fún ojó òla,
ìgbèyìn rè asì jásí adùn fún o.
Ìbí ti dá o pé, Máse tún aarà re dá.
Ki oluwa ki o ran o lowo ati emi naa
ReplyDeleteThe English translation of what he wrote is; May the Lord help you and me too.
ReplyDeleteAmen! Thank you sir
ReplyDeleteFearfully and wonderfully created...
ReplyDeleteKí olúwa mu o pò si ní ogbón,ìmò pèlú òye
ReplyDeleteAmen! Thank you.
Delete